Luke 6:37-38

Dídá ni lẹ́jọ́

37 a “Ẹ má ṣe dá ni lẹ́jọ́, a kì yóò sì dá yín lẹ́jọ́: ẹ má ṣe dá ni lẹ́bi, a kì yóò sì dá yín lẹ́bi: ẹ dáríjì, a ó sì dáríjì yín. 38 bẸ fi fún ni, a ó sì fi fún yín; òṣùwọ̀n dáradára, àkìmọ́lẹ̀, àti àmìpọ̀, àkúnwọ́sílẹ̀, ni a ó wọ́n si àyà yín: nítorí òṣùwọ̀n náà tí ẹ̀yin fi wọ́n, òun ni a ó padà fi wọ́n fún yín.”

Copyright information for YorBMYO